Shola Allyson – Mimo ni o Lyrics


0

Mimo ni O mimo ni O o mimo

Mimo ni O mimo ni O o mimo

 

Ad lib: Oluwa Olorun Eledumare t’O po n’ipa ati agbara

Gbogbo iseda nso bee emi naa mo so bee

Lat’ogbun emi i mi

 

Mo juba Re Oba mimo

Mo wole fun Oba toto

L’eyin Re, ko si o

Iwo nikan ni Oba

(Repeat)

 

Ad lib: Awamaridi Oluwa

Iwo t’O wa n’ipekun imole, Iwo ni ekun ola, ekun ogbon, ekun agabara

Oba t’Ó joko s’ori Ite, Oba t’Ó wa l’ori obiri aye maa s’ola a Re lo

 

 

Aye ati orun nbo O, kos’elomiin t’o ye ko gba ijuba wa bi o se’Wo

 

Mo wari fun O o Olola

Imole t’O ntan s’inu ookun mi ogo f’ooko Re

L’eyin Re ko si o

Iwo nikan ni Oba

L’eyin Re ko si o

Iwo nikan ni Oba

 

Ad lib: Pelu iwariri lat’ogbun emi mi

Kos’elomiin Iwo ni, l’eyin Re Iwo naa ni

Olugbemiro, Olusaaanuumi, Olukemi, Olufunmilebun, Olugbemiro, Iwo nikan Olutimileyin

 

Mimo ni O mimo ni O oo mimo

Aye ati orun ns’oro ogo Re a n f’ise owo Re han, Iwo, mimo

Mo da ohun mi po mo gbogbo ise Re, emi, emi i mi ati eemi i mi a nyin O nigbagbogbo, Oba t’Ó wa n’ipekun ola, ipekun ogo, ipekun agbara, ipekun ewa Iwo nikan ni Oluwa

Pipe naa l’O je Oluwa

 

Pipe ni O, pipe ni O o pipe

(Ta l’o le yo kuro ninu Re nigbat’a o tie mo)

 

Yiye ni O yiye ni O o yiye

(Iwo naa l’O wa fun’ra Re Iwo ni Oluwa, Odo Aguntan t’O joko s’ori Ite o yiye)

 

Tito ni O tito ni O o tito

(Tito ni O Eleda gbogbo iseda, Olutoju gbogbo eniyan, Olorun gbogbo eran ara, Eniti ngbo adura odo Re l’a nwa Iwo ni)

 

Gigun ni O gigun ni O o gigun

(Oba t’O joko s’ori obiri aye, O fi aye so’le s’ori awon isan omi, aye ò le ri lailai ko le ri ise e Re ni, gigun, o gun lailai)

 

Mo juba Re, Oba mimo, etc

 

Ad lib : Emi mi n juba Re nigbagbogbo

L’eyin Re kos’elomiin

I confess kos’elomiin

Olorun Eledumare t’O po n’ipa ati agbara Iwo ni o

Olorun awon’mo ogun Iwo nikan

Tani m ba juba bi o se’Wo

Olori egbegberun ogun awon angeli Iwo ni

Oluda aye kos’elomiin

Aseda gbogbo eniyan, Olorun gbogbo ede, Olorun gbogbo eya

Emi mi, eemi mi, ati emi naa

Imole t’o ntan ti ò le ku lailai

Olugbemiro, Olusaanuumi, Olugbamila, Oluyomi ninu okunkun

L’eyin Re ooo

Tani m ba sin bi o s’Enit’O gba mi la, Eniti mi ò ri sugbon ti mo r’ise Re ninu aye mi

 

Iwo nikan ni Oba

 

Ad lib: Olorun gbogbo araye Iwo nikan ni

Olutoju gbogbo eniyan Iwo nikan ni

Mo ki O ki O Iwo nikan ni Oba

Maa s’ola Re lo, maa s’ola Re lo kos’elomiin You Are The only One, You Are The only One Iwo nikan, Holy, mimo mimo ni O Iwo ni Oba

 

Iwo nikan ni Oba.


Like it? Share with your friends!

0

What's Your Reaction?

hate hate
0
hate
confused confused
0
confused
fail fail
0
fail
fun fun
0
fun
geeky geeky
0
geeky
love love
0
love
lol lol
0
lol
omg omg
0
omg
win win
0
win

0 Comments

Your email address will not be published. Required fields are marked *